WURA OUN JIGI

Isura Pataki,
Oun ti a n fi gbogbo okan wa,
Ba tun nitan, a tun kaya wa soke,
Eledumare lo fi jinki wa lookankan,
Dupe fun wura ti o fi fun o!
Wura elomiran ti di ewura,
Wura elomiran n dan gbinrin,
Oun gbogbo to tun n dan ko ni wura,
Bi ti Iya ko.

A ki ka kun,
Apere re lo n wa, wo jigi,
Asise re lo n ro; wo jigi.
A mura giri ka ma tun itan ikunna ko.
Bi jigi o ba si loko; Ijamba o jinna.
Bi o ba mu oju jigi re,
Inu eje loti jo bi imumu,
Bi o ba jo sokoto, wa jo kijipa.

Ati wura ati jigi,
Ko si eyi ti a o nilo,
Bo se owuro ati osan aiye eni,
Yera re wo,
Maro pe wura ni ye lori ju jigi lo,
E to Eledumare ni!
Wura oun jigi.

Aago Mewa koja iseju mewa owuro

26th August, 2013

(c)Olutayo IRAN-TIOLA, Lagos, Nigeria
No Comments Yet

Leave a Reply

Your email address will not be published.