WON TI KOJE!

Won ti ko oro won je,
Won o tun pe wa ni obo mo,
Won o to be lati pe wa ni ijimere mo,
A ti segun ede won,
Lo di fa fun Wole omo Soyinka,
A ti segun imo won,
Lo di fa fun opolopo ojogbon awawo dudu
Loke okun!
Amo owo won na,
Lo di fa fun gbogbo oko ti won n se ti a n gun.
A ti wa n gba won losise,
Awon oun alumoni ti Eledua fi jinki wa wu won,
Kosi funfun abi dudu mo,
Eniyan ni gbogbo wa,
Eebo ti ko oro re je!

4:57pm, 22nd July, 2014.
(c)Olutayo IRAN-TIOLA, Lagos, Nigeria
No Comments Yet

Leave a Reply

Your email address will not be published.