OLUSOSUN

Iru osun wo ni ka peyii?
Won mu e lo si eyin odi latijo,
O ti di aarin ilu wa yii,
A fi oorun tun ilu se.
Ogbooro lawon ti n sise lodo re,
Ogbooro nibu kun o lojumo,
Ogbooro ni ru eru wa fun o,
Ogbooro lo n je lati odo re.
Opo lona to wo nu re,
Gbogbo Ojota, Ikosi, Oregun lo n jadun re!
Ikini kaabo silu Eko,
Osun ojo kojo.
Ojo a ma ran oorun yii lowo,
Afere a ma tan ihinrere re,
Ojoro ladun re n je jade,
Olusosun, o ku aiye!

11th June, 2014

(c)Olutayo IRAN-TIOLA, Lagos, Nigeria
No Comments Yet

Leave a Reply

Your email address will not be published.