OLOJU KAN KI YIN ‘LORUN!

Oloju kan ki yin Olorun,
Ko dupe pe oju oun ni ri ran,
Ki yoo pe oun o ma fopa wo titi,
Ki sope wipe oun ki se alagbe,
Oloju kan ki yin Olorun!

Oloju ti ki yin ‘Lorun,
Ki ranti pe oun bi were,
Oun o foju sunkun omo,
Ki dupe wipe omo oun bi layo.

Ki sope pe oun o rin woja,
Ki mujo pe won o kawo ibi lejika re,

Ki’yo pe opa ounje o se mo oun lenu,
Ki sope wipe oun o so ise aje oun nu.

Ki ranti pe aisan oun san,
Ki ranti wipe iroyin ayo owon nile oun,
Ki mujo wipe balu oun o ja,
Ki sope wipe oko oun o fori sogi.

Ore mi Oloju kan re,
Ma ka iye oun ti owo re o to,
Ma gbagbe awon ewu to ti re o koja laimo,
Dupe nireti oun ti waa ri gba,
Dupe, Dupe, ki osi dupe,
Oloju kan mi yin ‘Lorun o!

15th Nov, 2013, 3pm

(c)Olutayo IRAN-TIOLA, Lagos, Nigeria
No Comments Yet

Leave a Reply

Your email address will not be published.