Ile iwosan,
Ile ijosin,
Ile oni nabi,
Bareeki orisirisi,
Obalende.
Ile gbigbe ni abi ti oja tita,
To san toru ni aye n lo,
Oko re losi gbogbo adugbo,
Ona re si Idumota,
Ona re si Ikoyi,
Ibi o ba n lo ni o so,
Obalende.
E ro ra se,
Boya omo olopa ni abi ologun,
To n fa gbo,
To n se asewo,
Pele, Pele o, Ajeji.
Abe afara kun fun eniyan,
Won n lo,
Won n bo,
Won n fera won,
Won n bimo,
Won n gbimo
Aje ire abi ti ibi,
Obalende.
Ariwo ge l’Obalende,
Ojulowo fonran ni,
Abi ti Alaba,
Ko si bi o se peto,
Wa l’Obalende.
Awon Hausa je o ni le,
Awon na ni opopona ti won,
Won n gun okada,
Won n ran so,
Won o gbeyin ni adugbo Obalende.
Wa woran,
Ma si tun woran,
Bo woran won a gbe o lo,
Boo woran ko ni ye o,
Obalende,
Omo Iya Inalende,
Ojulumo Kulende,
Nkan lo n le gbogbo won.
11:28pm, 17th May, 2013