EKO

…ilu odaju

LAARO
Won a ji loworu kutukutu,
Won a daju wia,
Won a mura giri,
Won a mu irin ajo pon,
Won a morile ibise:
Oko ero le je ti awon ole idaji,
Oko ara eni leje ounje olopa.
Owuro lojo lotito,
Ere tete lese,
A mo sa!
Ko so pe ijamba oko oniwaye,
Ko so pe ka ma sepe,
Ko so pe omo igboro oni soose,
Ko so pe ole o nija,
Won o da ogun sile laarin oja,
Won a tun pa iro fun on raja,
Won a tun ke pe Olorun.
Eko: ilu odaju.

LOOSAN
Nibiti won ti n jeun,
Won a tun ma petepero,
Lori eniti o se won,
Bo se won: oran,
Bi won se o: oran.
Won a rerin ika,
Won a fise yora won leyin,
Beeni won a ma duro oja ra,
Won a ma rin bi eniti o nijanu.
Won o rojo elejo,
Yeye repe.
Won agbe ebi falare,
Won a gbe ara felebi,
Eko: ilu odaju.

LAALE
Ija oju popo,
Oko ero abi teni,
Ki se suuru fun ara won,
Gbogbo re a loju po,
Won a tun ma raja je,
Ki ebi ma pa inu,
Won a tun ma sare lo sile,
Iberu bojo re lara won,
Ookun: o meni owo,
Sugbon afipa gba owo
Joko ti o ni paraga*,
Ise aje ni gbogbo won n se:
Botona, bi otana.
Ati ma pada si ilu oke lofo ni,
Ki ola le da na ni,
A mo sa!
Ilu odaju l’Eko.

* Paraga ni oruko awon oti lile igbayi

(c)Olutayo IRAN-TIOLA, Lagos, Nigeria
No Comments Yet

Leave a Reply

Your email address will not be published.