AWA SOPE OLORUN IKOORE

Lati ibere pepe,
Ni asiko ojo,
Asiko Erun,
Asiko otutu,
Asiko Oru,
Asiko gbigbin,
Asiko ikoore!
Olorun ninu ogbon re lo da won!
Asiko ikoore,
Ni mu ka ranti imisi Olorun,
Olorun misi ile lakoko,
O jade kuro ninu Ibu Omi,
Olorun mi si ile,
Eso orisirisi si jade wa,
Olorun mi si erupe,
Eniyan jade wa,
Imisi Olorun lo mu opo de!
Awa de tilu ti fon,
Awa de tayo tayo,
Awa mu lati inu ikoore wa,
A dupe, a sope, a mujo, ayo niwaju Eledumare,
Akore oun ti a gbin,
Akore ife Olorun,
Akore ibukun Olorun,
Ki le tun fe?
E tuju ka,
Oro yin yoo dayo ju bayi lo,
Igba die lo ku!
Olorun a wa n fe,
Ile to la re wa,
Ayo ibugbe re,
Ju gbogbo ayo lo!
Emi n bo Kankan,
Ere mi si n be pelu mi,
Lati san fun onikaluku,
Gegebi ise owo re yoo ti ri,
Baba ati Mama,
Omode ati agba,
Isokunrin, Isobinrin,
Se e n mura fun ikore awon ayanfe,
O de tan o!
Ma fi se faari o!
6thNovember, 2012
(c)Olutayo IRAN-TIOLA, Lagos, Nigeria
No Comments Yet

Leave a Reply

Your email address will not be published.